Bii ajẹ to jẹ̣ eepo ọbọ ni ọdomọkunrin kan, Arowolo Ibrahim, ṣe n ka pẹlu awọn ẹlẹgbẹ ẹ ti wọn jọ digunjale, nigba ti kọmiṣanna ọlọpaa ṣafihan wọn han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, niluu Abẹokuta, l’Ọjọruu, Wẹsidee, nigba ti wọn ko wọn dewaju awọn oniroyin.
Mẹrin lawọn janduku ọmọ keekeeke yii ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejidinlogun si mẹrinlelogun. Awọn eeyan naa niwonyi; Arowolo Ibrahim, Yakubu Ibrahim, Yusuf Alani Azeez, Ṣowẹmimọ Faruq ati Peter Okenu, ọmọ Ibo ti wọn loun lo ṣatọna wọn debẹ
Негізгі бет Arowolo atawọn ẹgbẹ ẹ ti wọn lọọ digun ja ọmọ Ibo lole ti jẹwọ
Пікірлер: 13