Abẹ́ná ìmọ̀ wa, Ọmọ-ọba Lawal Taofeek (Alábẹ́rẹ́) tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ọ̀dọ́ tó mọ ojúlówó ìtàn gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Àlí Okùnmádé tó jẹ́ Balógun ìlú Ìwó tó tẹ̀dó sí Ìbàdàn lọ́dún 1864 ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìtàn Akọni pàtàkì yìí.
Lára ohun tí Ọmọ-ọba yìí fẹ̀ lójú ni ìtàn tó rọ̀ mọ́ ìdí tí wọ́n fi ń pe àwọn ọmọ Àlí Ìwó ní, Ọmọ-ọba méje; Sòún, Olúwòó, Olúfọ́n, Ọ̀fà, Ọlọ́rọ̀, Ajagunlaase àti Olómù.
Ẹ fara balẹ̀ wò ó, láti mọ̀ nípa ìran Olúbàdàn titun tí yóò gbọ̀pá ìṣàkóso ilẹ̀ Ìbàdàn ní Ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹta, ọdún 2022.
Негізгі бет ITAN ALI OKUNMADE (ALI IWO)
Пікірлер